Ipa TÍ KÍkỌ́ Ẹ̀kỌ́ IlÉ NÍnÚ ÈtÒ KÒrÍkÚlỌ́Ọ̀mÙ YorÙbÁ N KÓ LÓrÍ Ẹ̀kỌ́ Àti ÀwÙjọ Òde ÒnÍ
Student: Bisola Sileola Olabanji (Project, 2025)
Department of Education and Yoruba
Ekiti State University, Ado-Ekiti, Ekiti State
Abstract
Iṣé ìwádìí yìí ṣe àfihàn ipa tí kíkọ́ ẹ̀kọ́ ilé nínú ètò kòríkúlọ́ọ̀mù Yorùbá n kó lórí ẹ̀kọ̀ àti àwùjọ òde òní. Ẹ̀kọ́ ilé jẹ́ kókó pàtàkì nínú ìlànà ẹ̀kọ́ àti ìtọ́nà ìwà ní àárín àwùjọ Yorùbá. Ìlànà yìí jọmọ̀ bí a ṣe ń kọ àwọn ọmọ nípa ìwà ọmọlúwàbí, èdè, àsà, àti ìbàsẹpò tó tọ́. Ìlànà ẹ̀kọ́ ilé kì í ṣe èyí tí a gbà nílé ìwé nìkan, ṣùgbọ́n ó tún jẹ́ ẹ̀kọ́ tí a gbé kalẹ̀ láti inú ìdílé àti àwùjọ fún ìdide àti ìdàgbàsókè ọmọ. Nínú àwùjọ Yorùbá, ẹ̀kọ́ ilé ní ipa tó ṣe pàtàkì nínú títọ́jú èdè àti ìdàgbàsókè àṣà. Gẹ́gẹ́ bí àwọn àkọ̀tán àti àpẹẹrẹ tó wà, a mọ̀ pé èdè Yorùbá ní òpa ìtìléyìn fún àsà àti ìsè wà, ó sì jẹ́ ohun èlò pàtàkì fún ìdàgbàsókè àwùjọ. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ loní kò ní ànfààní tó yẹ láti kọ ẹ̀kọ́ nipa àṣà àti ìṣe ìbílẹ̀ wọn, torí pé ẹ̀kọ́ ilé ti dínkù nínú ètò ẹ̀kọ́ àkànṣe. Kí ọjọ́ báà le dá, o ṣe pàtàkì ki à gbìyànjú láti tún ẹ̀kọ́ ilé ni ṣíṣe àti kíkọ rẹ̀ sínú ètò kòríkúlọ́ọ̀mù Yorùbá. Èyí ló mú kí ìwádìí yìí ṣe pàtàkì, láti tọ́jú àṣà àti èdè Yorùbá nípasẹ̀ mímú ẹ̀kọ́ ilé padà sínú kòríkúlọ́ọ̀mù Yorùbá. Nípasẹ̀ ìwádìí yìí, à ó gbìyànjú láti fi ipa tí ẹ̀kọ́ ilé ní lórí ẹ̀kọ́ àti àwùjọ lónìí hàn, àti láti ṣàbẹ̀wò sí àwọn ìṣòro tó dojú kọ́ wọ́n, kí a sì pèsè ojútùú tí yóò jẹ́ àǹfàní fún àwùjọ. Ni àkótán, ẹ̀kọ́ ilé gbọdọ̀ gba ipo tó yẹ nínú ètò ẹ̀kọ́ Yorùbá kó má bàa ṣòfò, kó sì le jèrè òye àti àmi ìdánimò fún gbogbo ènìyàn. Bí Yorùbá tí wi, “Ọmọ tí a kò kó, ní yóò gbé ilé tí a kó tà.” O pọn dandan kí a tún ilé ṣe kí ilé má bàa bàjẹ́.
Keywords
For the full publication, please contact the author directly at: olabanjibisola6@gmail.com
Filters
Institutions
- Adeseun Ogundoyin Polytechnic, Eruwa, Oyo State 1
- Adeyemi College of Education, Ondo State. (affl To Oau, Ile-Ife) 68
- Ahmadu Bello University, Zaria, Kaduna State 101
- Air Force Institute of Technology (Degree), Kaduna, Kaduna State 11
- Air Force Institute of Technology, Kaduna, Kaduna State 2
- Akanu Ibiam Federal Polytechnic, Unwana, Afikpo, Ebonyi State 6
- Akwa Ibom State University, Ikot-Akpaden, Akwa Ibom State 53
- Akwa Ibom State College of Edu, Afaha-Nsit (Affl To Uni Uyo), Akwa Ibom State 2
- AKWA-IBOM STATE POLYTECHNIC (IEI), IKOT-OSURUA, AKWA IBOM STATE 41
- Akwa-Ibom State Polytechnic, Ikot-Osurua, Akwa Ibom State 32